05/04/2026
AGBADO - MAIZE
Ohun-ọgbin ti o wulo lọpọlọpọ jakejado ayé ni agbado jasi; on kannaa ni awọn Ẹ̀gbá npe ni ọka, awọn miran si npe ni yangan. Awọn oyinbo kan ti o sọrọ agbado sinu iwe wọn li o sọ pe ilẹ Amẹrika l’ọhun ni ilẹ agbado, ati pe lati ibẹ lati tu u ka lọ de ibomiran li ayé. Bi eyi ba jẹ bẹẹ l’oju Oyinbo ko daju pe awa Dudu ni ilẹ Yoruba nihin jẹ gba a si bẹẹ, kaka bẹẹ ohun ti awa le sọ ni pe, agbado jẹ ohun-ọgbin kan ti Ọlọrun da mọ ilu tiwa nihin lati ọjọ-jọjọ ọhun-l’ọhun wá, ati pe kii ṣe lati ilu okeere kan li a ti mu u wa de ihin yi.
Onjẹ taara ni agbado si jẹ ni ilu-kilu ati ilẹ-kilẹ ti a mba a pade, nwọn ibaa jẹ ti eniyan dudu, tabi pupa, tabi ofeefee. Bi a ko ti dá a mọ́ awọn eniyan funfun naa to, sibẹ nwọn ko nkọ lati jẹ ẹ́ nigbati o ba bọ si irọrun fun wọn. Nwọn tilẹ ti wa ọna ti nwọn fi pa a da si bi o ti le dùn mọ wọn fun jijẹ, tobẹẹ ti o fẹrẹ ma si ọjọ kan ti Oyinbo kii ṣalai jẹ ohun ti njẹ agbado, nitoripe awọn naa ka á sí onjẹ ti ifun eniyan li ara-lile ati agbara tabi okun-ninu.
Ọpọlọpọ awọn eniyan li wọn gbadun jijẹ agbado ni tutu ju igbati o ti gbẹ tan lọ, ati nigbanaa, nṣe li a ma nsun un tabi ki a se e. Ọpọlọpọ ko ma si kọ gbigbẹ rẹ o. Nwọn a maa yán an ninu ìṣasùn; onjẹ ni nibagbogbo ṣa. Bẹẹ si ni nigbati a ba nmu Ẹkọ-adawamu tabi ti a gbe akaṣu bẹ́ ilẹ̀. ‘Cornflour’ naa ati Burẹdi t’oun Bisikiti ti o wá lati ọdọ Oyinbo, ko si eyi ti o jẹ pe kii ṣe inu agbado ni nwọn ti ni ibẹrẹ. Nwọn si dun-ún mu lọ ẹnu kọja si ọna ọfun; nwọn a si maa dún jigbun lọ odo ikun.
Laiṣe aniani oriṣiriṣi ọna iwọnyi ti a darukọ to jẹ pe a maa nlo agbado si kọ li o mọ. Awọn miran si le wa ti awa ko mọ ni ilẹ wa nihin; A sì rò wipe lẹhin alikama ati irẹsi, ko si ọgbin oniwóró ti a tun nṣe ọgbin rẹ pupọ to ti agbado.
Ti wóró tabi ọmọ-inu agbado papa li a nsọrọ rẹ yi; bi eniyan si ti njẹ ẹ pupọpupọ tó, bẹẹ naa li o si njẹ onjẹ oniruuru ẹranko ti igbo ati ti ile, ni ilu gbogbo.
Lẹhin ti ọmọ-inu agbado tikararẹ, awọn nnkan miran wa ti a tun nlo l’ara agbado:
1.Poroporo tabi igi rẹ ni nwọn fi nṣe iyọ-oyinbo;
2.Ewe rẹ ni nwọn fi nṣe takada;
3.Haha rẹ ni nwọn fi nki timtim ati irọri;
4.Kuku rẹ si ni nwọn fi nko‘na dipo igi.
Nigbati a o ba ṣe ọgbin agbado, a ko gbọdọ má ṣe itọju ilẹ ti a o gbin in sí ki o dara gẹgẹ bi ti awọn ọgbin miran; bi agbado ba si ti hu jade, t**i naa ni agbẹ ni maa tọju rẹ ki èpò ati koriko maṣe ba a ja ati ki o ma fún un lọrun t**i yi oo fi gbó. Kii pẹ rara, oṣù mẹta ṣa ni, agbado ti gbo, o si ti to ya ki a si ma jẹ ẹ. Ko si ilẹ ti ko dara fun agbado lati hu si. Biotiwu ki ilẹ naa ti ṣa to fun ọgbin miran, agbado yi oo hu nibẹ, yio si pọn-mọ pẹlu, akaṣe ọmọ rẹ a jẹ ọlọmọ-sikata. Agbado tun gọ̀ ni hihu ni ibikibi ti o bọ si tobẹẹ tó bí o tilẹ jẹ ata-ọna ni, bi o ba jàjà ri juujuu bora nibẹ, ti adiẹ ko si fi oju gaani rẹ, yio hu naa ni, yi oo si fẹ́ fẹ ọla pẹlu. Sibẹ naa, ilẹ ti o dara ti a si bojuto li o yẹ ki a ṣe ọgbin agbado si; iṣẹ agbẹ ko ni yọri si aṣedanu ni igba naa.
Lẹhin ọjọ marun, ti a ti ri wóró agbado mọlẹ, yi oo sọ jade yi oo si bẹrẹsi maa dagba lọ, bi idiwọ kan kò bá bá a. Oṣù kan l’ẹhin eyi, yi oo ga to bi ẹsẹ meji ni iwọn, diẹdiẹ si i yi oo ma tu ọ̀jẹ́rẹ́ tẹle e; yi oo si tun maa ga siwaju. Kii pẹ naa tẹle eyi kini kan yio ma su yọ l’ẹgbẹ igi rẹ l’ọtun l’osi ti, bi ọjọ ba ti npọ to l’ori wọn, nwọn a maa tobi si i, - eyi li a npe ni “agbado npọn’mọ”; igi agbado kọọkan a maa ni to mẹta tabi mẹrin, omiran a maa ni jubẹẹ lọ bi ilẹ ba dara fun un.
A ko gbọdọ gbagbe pe ohun-ọgbin ti o fẹ omi lati maa mu u dagba ni agbado jẹ, nitorinaa a ni lati ṣe itọju pe ki omi ma ṣe wọ́n ọn. Nitori eyi, sáà ti yi oo jẹ kongẹ ojo ni agbẹ nfiyè si lati gbin agbado. Bi agbẹ ba kanju ju tabi ki o kẹhin ju, ti omi ko to fun agbado, rẹurẹu bayi ni agbado igba bẹẹ ma nri; a si ko ibanujẹ ba oluwa rẹ. Lẹhin oṣu mẹta ti agbado ti ndagba, ewe ara rẹ a maa pọn, ti o jẹ apẹrẹ pe agbado ngbo, agbẹ ko si njafara rara nigbati o ba ti ri eyi, ati ni werewere naa tẹle eyi li a o maa gbọ igbe kakiri igboro wipe, - “Oṣingin ‘gbado,” – “Olóko-kò-gbowó.”
Aṣẹṣẹ yọ agbado ni nwọn ma npolówó kiri bẹẹ.