22/11/2022
*OLÚRÓNBÍ*
Ní ìgbà láéláé, arábìnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúrónbí. Obìnrin yìí fi ẹkún sùngbérè ọmọ nílé ọkọ. Kò rí ọmọ gbé jó, ó ń fi ọwọ́ osùn nu ògiri gbígbẹ, inú rẹ̀ a sì máa bàjẹ́ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà.
Ó sa gbogbo ipá láti le fi inú ṣoyún, ṣùgbọ́n pàbó ni gbogbo ìlàkàkà rẹ̀ ń já sí. Èyí ló múu pinnu láti lọ sí ọ̀dọ̀ igi ìrókò, bóyá àníyàn òun le è di mímúṣẹ. Bí ẹrù bá ṣáà kọ òkè, tí ó tún kọ ilẹ̀, ó níbi à ń gbé e kà.
Ìrókò jẹ́ igi alágbára tí àwọn ènìyàn ń bọ, tí wọ́n sì ma ń béèrè ohun tí wọ́n bá fẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Bí wọ́n bá ti béèrè fún ohun tí wọ́n fẹ́, àwọn pàápàá á jẹ́ ẹ̀jẹ́ ohun tí wọn yóò wá fi dúpẹ́ bí olúwéré bá ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ àníyàn wọn.
Olúrónbí gbéra, ó gba ọ̀dọ̀ ìrókò olúwéré lọ, ó fi omijé ojú béèrè ọmọ lọ́wọ́ ìrókò, Olúrónbí sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti dá ọmọ yìí padà fún ìrókò, àní kí òun ṣáà rí ọmọ gbé jó, kí aráyé tilẹ̀ fi orúkọ ọmọ pé òun, bó tilẹ̀ jẹ́ fún ọjọ́ kan. Olúrónbí gbàgbé wípé láti jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ yùngbàyugba, ṣùgbọ́n àti san owó ẹ̀ tìkọ̀tikọ. Inú ìrókò olúwéré dùn, ìdí sì ni wípé, nínú gbogbo àwọn tí wọ́n ti ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ níwájú rẹ̀, kòì tíì sí èyítí ó jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ bàǹtàbanta bíi ti Olúrónbí yìí rí. Ẹ̀jẹ́ tí ó tóbi jù tí àwọn ènìyàn ń fún olúwéré ni ewúrẹ́ àti àgùntàn.
Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, Olúrónbí fi'nú ṣe oyún, ó bímọ obìnrin, ẹ̀gàn rẹ̀ di ògo, inú ọkọ rẹ̀ pàápàá dùn. Kódà àláárì ni aṣọ tí wọ́n wọ̀ lọ́jọ́ ìsọmọlórúkọ. Wọ́n fi'lé pọn ọtí, wọ́n fi ọ̀nà ro ọkà, iyán àti ìrẹsì ò gbẹ́yìn. Ẹmu ogùrọ̀, bùrùkùtù, ọtí àgàdàngí, àti àwọn ọtí ẹlẹ́rìdòdò kò gbẹ́yìn. Eléré àpàlà, bọ̀lọ̀jọ̀ àti wéré ló ṣeré lọ́jọ́ ọ̀hún. Apọ́nbéporẹ́ ni orúkọ tí wọ́n sọ ọmọ, ìdí sì ni wípé, ọmọ náà pupa fòò, ara rẹ̀ tutù nini, ó ń dán gbinrin bíi jígí, kò ní àbàwọ́n kankan bítiíwù ó mọ, Apọ́nbéporẹ́ rẹwà púpọ̀.
Ọjọ́ ń gorí ọjọ́, ọdún sì ń gorí ọdún, Apọ́nbéporẹ́ ń dàgbà, ṣùgbọ́n Olúrónbí ti gbàgbé ẹ̀jẹ́, ó ti gbàgbé ìmùlẹ̀, ó ti gbàgbé ọ̀rọ̀ àjọsọ, ọjọ́ oore ti pẹ́, asiwèrè sì ti gbàgbé. Ìrókò olúwéré pàápàá ti ń retí ẹ̀jẹ́, nígbàtí kò sì ríi ló múu pinnu láti bẹ ilé O