Ọmọ Òdò Àgbà

Ọmọ Òdò Àgbà

Share

Kábíèsí oo!! Kábíèsì ooo!!!.

Mo fi ojú-èwè yìí sọri Ọlọ́run Elédùmarè, Ọba ọlọ́wọ́ gbọgbọrọ tó kárí ayé. Ọlọ́run ìyìn, Ọba tí kìí sàbòsí, Ọba tí kìí sún, Ọba tí kì í tòrùgbé, Alákóso ìgbà, Ọba mi ẹ̀rù-jẹ̀jẹ̀ apòtákú-fin-ín-fin-ín, Ọba mo da ọ lólá tí kò sí eni tí ó le mú ni kúrò nípò olá, Ọba mi, mo ta ọ́ lósì tí kòsí bàbá eni tí ó le múni kúrò nípò òsì Kábíèsí o!

Photos 18/02/2023

Bí á bá se sísé onísé là á se tara eni, ìwo omo isé to ń físé ògá rè sàfàlà, múra sí dáadáa, ìwo tògá rè ó gbodò yó'dì boro, b'ògá bá ti fi sóóbù sílè tàbí bójú ba po fírí, kí elòmíràn ó gbówó ojà ògá sálà ni, ònà bí yóò se je é keegun ni omíràn yóò máa sán, bíí kí wón tajà, kí wón ó má kówó jísé, sùgbón bá ò kú, ìse ò tan, èdá tí kò gba kádàrá, à gba kodoro...... Kò kúkú séèyàn mó láyé!

Béè a kò rójà tà mó dàbí alárà. Ogun wó sóóbù, wó sóóbù táwon ìjoba gùnlé kò tilè jé kí a fèdó lórí òróòrò lójà òhun. Àmó sá! Nínú òfíì, nínú òólà ni omo páǹdòrò ń dàgbà....

Ní ti òrò àwon omo òdo ìtájà; ojú to bá dilè ni ìroré ń so.....

Ó mú mi rántí ìtàn Àáyá àti olóko.
Àáyá àti ìyàwó rè ni wón bó sóko àgbàdo. Gégé bí e se mò pé edun féràn àgbàdo ju gbogbo oúnje lo. Kí olóko ó tó dé, wón ti yàgbàdo lo bí ilè, bí ení. Ní kò kò kò tí wón ń gbóròó esè olóko, ni wón ti bo bérébéré sí abé ègbìnrìn kan. Inú bí olóko bí àwon àáyá se je àgbàdo yìí, kò mo ìgbà tí ó so jáde pé bí ó bá ti dòla, òun ń ó kó àwon òré è mi bò láti wá ya gbogbo àgbàdo tó kú. Ó pèyìndà lójó náà lòhun.

Bí ilè se ń mó ní ojó kejì ni ìyàwó àáyá lo jí oko rè pé, ó yá lóko. Àáyá so fún ìyàwó rè pé àwon kò gbodò lo nítorí olóko so pé òun ń kó àwon òré rè bò láti wá ya gbogbo àgbàdo tó ku lójó náà, ìyàwó àáyá so fún oko rè pé kí ó má fòyà, àti pé ìlérí asán ni olóko se. Tòhunténu, àáyá, ìyàwó àáyá àti gbogbo àwon omo won bó sóko àgbàdo, isé bèrè, wón forin sénu bí wón se woko, ó bá di:
Edún yàgbàdo
Hàá!
Edún yàgbàdo
Hàá!
Edú yàgbàdo
Hàá!
Bí wón se tún gbóròó esè olóko ni wón sá pamó, inú bí olóko digidigi. Kò mo ìgbà tó tún sèlérí pé òun àti ebí òun ni àwon yóò jo jí sóko yìí láti wá ya gbogbo àgbàdo ti àwon olórí-boobo yìí je kù. Ó wí pé se bí àwon àáyá olórí burúkú yìí kò bá ti rí àgbàdo je mó, wón yóò fi oko òun sílè. Ò sòrò dà sílè, ò gba ilé rè lo.

Bí ilè se tún mó ní ojó kejì ni ìyàwó tún lo jí oko rè pé ó yá lóko àná, enú ya àáyá ó wí pé se bí ìyàwó òun gbó tí olóko so pé òun àti àwon ebí òun ni yóò jí wá ya gbogbo àgbàdo tó kú lónìí.

Láì fa òrò gùn, àáyá, ìyàwó rè àti àwon omo wón tún forí lé oko àgbàdo gégé bí ìse won. Ó tún di:
Edún yàgbàdo
Hàá!
Edún yàgbàdo
Hàá!
Edún yàgbàdo
Hàá!
Bí wón tún se gbúròòó esè olóko ni wón bo bérébéré. Olóko férè le è fórí gbálè lówó ìbínú. Kò mo ìgbà tó se ipinnu pé bí ilè bá ti mo lóla, òun yóò kò ìbon àti àpò wá láti wá ya gbogbo àgbàdo òun. Òun kò jé fi dá enikéni mó. Ó mú ònà ilú pòn. Àwon àáyá náà fórí lé inú egàn.

Bí ilè ti ń mó ní ojó kejì, àáyá ń retí aya rè kí ó wá jíi ní àkókò tí ó máa ń wá sùgbón oníyen kò wá. Ara rè kò gbà á mó, èpà àná ti dún mo ehoro rè lénu. Ó dìde, ó sì lo bá ìyàwó rè pè òun ti ń retí rè gégé bí i ìse rè àti pé oko àgbàdo ti yá. Ìyàwó rè dá a lóhùn pé àwon kò le è lo sóko lójó náà nítorí pé ewu ḿbẹ lóko. Ó so fún oko rè pé níwòn ìgbà tí olóko ti le è so pé fúnra òun ni yóò wá sóko lójó náà láì fi isé náà dá eni kankan mó, yóò wá ló so yen, bí ó ná jé pé ó sí ń fi dá ènìyàn ni, ohunkóhun kò ní i se....

Isé máa ń di síse, bí onísé bá wà nìdìí isé rè, sùgbón ní kété tí ó bá ti pèyìndà, isé náà pèyìndà nìyen. Àwon ènìyàn máa ń fi isé ráre ni bí kò bá ti si onísé nìdìí rè. Èyin ògá isé náà, e máa fisé pómo isé lorí. Ìwo omo isé náà to kúndùn àsà ibi a tíise là á ti ń jé, ma sògá rè dédún a rínlè, òní lári.......

E kú ojúmó èyin èèyàn wa, a kú àríyá òpin òsè, Olúwa kòní se èyí l'òpin fun gbogbo wa oo! (Àse Edùmarè)

02/09/2016

Bi a bá wí pé eégún nle ’ni l’óko yangan, kò ye ki Pákòkò le ’ni l’óko àgbàdo.

27/06/2015

Twitter àti Instagram e tèlé mi lórí ìtakun yìí : ohun ti a fi ń wu aráwa lójoojúmọ́ èmi be Olórun Oba kó ma bàjé láèláè.

Photos 15/02/2015

L’áyé ojóun, kò sí ìwé kíko sílè. Nítorí náà kò sí àkosílè rárá nípa ìtàn ìbèrèpèpè èyà tí ó ń jé Yorùbá. Ìtàn àtenudénu nìkan ni a lè fi enu kò sí bí àbòwábá . Nítorí náà, ó jé àsà káàkiri kí orísìírisí èyà máa gbìyànjú láti wá ìtàn àtenudénu láti gbe ìbèrèpèpè won lésè pàápàá bí ó bá se wí pé èyà béè kò ní àkosílè ìtàn ìsèdálè àwon baba-ńlá won.

Lénu àwon òpìtàn ni a ti ń gbó ohun tí ó se pàtàkì ní Ayé àtijó. Àwon òpìtàn wònyìí kò ní isé méjì àfi kí wón máa so àwon ohun tí ó se pàtàkì ní ìgbésí Ayé àwon Yorùbá. Ààfin oba sì ni àwon òpìtàn yìí ń gbé. Nítorí náà, bí a bá ń sòrò nípa ìsèdálè tàbí ìsèǹb’áyé tàbí ìbèrèpèpè àwon Yorùbá, èyí tí a gbó lénu won, àti ìwádìí tí àwa náà bá se ní a lè tóka sí. Ìdí nìyí tí ó fi sòro láti so pàtó pé ibi báyìí ni àwon Yorùbá ti wá àti pé àsìkò báyìí ni wón bèrèsí dó sórí ilè di òní olónìí.

Nítorí náà, orísìírisí ni àwon ìtàn tí a ti gbó nípa ìsèǹbáyé àwon Yorùbá. Èkínní ni pé ìlú Mékà ni ilè àwon Áráàbù (lárúbáwá) ni wón ti wá. Wón rìn wá láti dó sórí ilè tí wón wà di òní olónìí. Gégé bí ìtàn yìí, mòlébí kan náà ni èyà Yorùbá àti èyà kan tí à ń pè ní Gògòbírí àti èyà Kòkáwà ní ilè Haúsá. Omo Lámúrúdu tí ó bí Odùduwà ni wón ń se.

A gbó pé rògbòdìyàn kan ni ó sèlè ní ilè Mékà tí ó mú Odùduwà, àrólé Oba Mékà nígbà náà kúrò ní ìlú. Ìjà yìí selè láàrin àwon elésìn Mùsùlùmí àti àwon tí wón ń pè ní “Abòrìṣà”. Abòrìṣà hanúnhánún sì ni Odùduwà. Nígbà tí wón ní kí àwon Abòrìṣà wònyìí kúrò láàrin ìlú ni àwon pèlú Odùduwà wá tedó sí Ifè níbi tí èyà Yorùbá gbà pé ó jé orírun won báyìí....

Nibi yìí ni máa dúró si lónìí, a ó tún ma tẹ̀síwájú nígbà mìíràn... Èmi ni ti yín tòótó Olámidé Omo Òdò Àgbà!!!

24/12/2014

Nítòótọ́ ojú dáradára ni ẹ̀tàn, ẹwà sì jásí asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Olúwa ni kí a fi ìyìn fún un (Ìwé Òwe 31:10-31).

10/12/2014

Èmi o kánjú kọjá kádàrá, èmi ò kanjú kọjá ẹ̀mí mi, N tọ́wọ́ mi ó to,mi ó jẹ́ fi gọgọ fàá! Máse kánjú tú olú-ọrán, igba rẹ̀ kò tóó sè lọ́bẹ̀.

Want your school to be the top-listed School/college in Lagos?

Click here to claim your Sponsored Listing.

Location

Category

Website

Address


Lagos