01/03/2025
Kò Sẹ́ni Tó Ní Ìdí Láti Yin Olúwa Àfi Ọkàn Alààyè
Ẹ̀yin ará nínú Kristi,
Lónìí, a óò máa kọ́ ẹ̀kọ́ lóríi kíni ó túnmọ̀ sí láti jẹ́ ọkàn alãye àti ìdí tí àwọn ẹ̀mí alãye nìkan ní ìdí láti yín Olúwa.
Kíni Ọkàn tàbí Ẹ̀mí Alààyè jẹ́?
Alààyè ọkàn ni ẹnìkan tí ó ti gba Jésù Kristì gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà wọn, àti àwọn tí a ti tipasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run sọ di àtúnbí tàbí ẹ̀dá titun(Johannu 3: 3-6). Alààyè ọkàn ni a fihàn nípa ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run, ìgbọràn wọn sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, àti ìfẹ́-inú wọn láti sìn ín lí ẹ̀mí àti lí òtítọ́.
Kíni Ẹ̀mí Alààyè Léè Ṣe (Ìdí Tí A Fi Dá Ọ Gẹ́gẹ́ Bí Alààyè Ọkàn 1)?
Gẹ́gẹ́bí ẹ̀mí alãye, o ní agbára láti:
- Yin Ọlọrun, kí o sì jọ́sìn Rẹ̀ (Orin Dafidi 103:1-5).
- Sin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ (Deuteronomi 10: 12-13).
- Sọ̀rọ̀ ìhìn rere Jésù Kristì Olùgbàlà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn (Mátíù 28:18-20).
- Gbé ìgbésí ayé ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Jòhánù 14:15).
- So èso fún ìjọba Ọlọ́run (Johannu 15: 1-8).
Kíni Ọkàn Alààyè Léè Yípadà (Ìdí Tí A Fi Dá Ọ Gẹ́gẹ́ Bí Alààyè Ọkàn 2)?
Gẹ́gẹ́bí ẹ̀mi alãye, o ní agbára láti:
- Ba gbogbo iṣẹ́ àti agbára okunkun jẹ́, kí o sì yí ìpinnu búburú wọ́n padà sí rere (1 Johannu 3: 8).
- Gba ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ṣèkẹ́ṣẹkẹ̀ àti ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 6: 17-18)
- Dáríjì àwọn ẹlòmíràn kí o sì gba ìdáríjì (Matteu 6: 14-15)
- Gbé ìgbé ayé ìṣẹ́gun lórí ọ̀tá (1 Kọ́ríńtì 15:57)
Kí Ni Ọlọ́run Ǹretí Lọ́wọ́ Ọkàn Alààyè?
Àwọn ǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run ńretí lọ́wọ́ alààyè ọkàn:
- Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn, ẹ̀mí àti èrò inú rẹ (Matteu 22:37-40).
- Ṣègbọnràn sí àwọn àṣẹ Rẹ̀ (Jòhánù 14:15).
- Máa sìn àwọn ẹlòmíràn nínú ìfẹ́ (Gálátíà 5:13-14).
- Jẹ́rìí sí oore Rẹ̀ (Orin Dafidi 96: 2-3).
Kíni Ó Ńyọrísí Ìparun Ayérayé?
Àwọn ǹkan wọ̀nyí a máa yọrí sí ìparun ayérayé
- Tí ènìyàn bá kọ ìfẹ́ àti ìgbàlà Ọlọrun (Johannu 3:36).
- Tí ènìyàn bá tẹ̀síwájú nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìgbọràn (Heberu 10: 26-27).
- Tí ènìyàn bá kùnà láti dáríjì àwọn ẹlòmíràn (Matteu 6: 14-15)
- Tí ènìyàn bá ńgbé ìgbésí ayé ìmọtara-ẹni nìkan àti ìgbéraga (Owe 16:18)
Jẹ́ kí a wo àpẹẹrẹ méjì láti inú ìtan-àkọọ́lẹ̀ inú ìwé mímọ́:
Ìtàn Dáníẹ́lì
Dáníẹ́lì, olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe pásítọ̀ alákòókò kíkún, ṣùgbọ́n ó gbé ìgbésí ayé ìgbọràn àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run. Ó kọ̀ láti ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́, pàápàá ní ojú ewu àti inúnibíni ( Danieli 1: 8-16; 3: 16-18, 6: 1-28 ). A gbóríyìn fún bí o ṣe jẹ́ olóòtító nípasẹ bí ọba ṣe dáa lọ́lá tí o sì gbéega sí ipò agbára àti ìyí.
Ìtàn Júdásì Ísíkáríọ́tù
Júdásì ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù méjìlá, fara hàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìwọra àti ìmọtara-ẹni-nìkan ló sún un sí ìkọ̀kọ̀. Ó da Jésù fún ọgbọ̀n ẹyọ owó fàdákà, èyí yọrí sí dídá Jésù mọ́ àti bí wọ́n ṣe kàn án mọ́gi (Mátíù 26:14-16, 47-50). Iṣẹ́ àti ìwà Júdásì mú k'ó yọrí ìrìn àjò rẹ̀ sí ìparun (Iṣe Awọn Aposteli 1:18-19).
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti Ìwòye Síwájú síi:
Ya àkókò díẹ̀ sọ́tọ̀ láti ṣ'àṣàrò lórí àwọn ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀nyí:
— Sáàmù 103:1-5 — Jòhánù 3:3-6 — Róòmù 6:17-18 — 1 Kọ́ríńtì 15:57
Béèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́wọ́ ara rẹ:
1. Kíni ó túnmọ̀ sí láti jẹ́ ẹ̀mí alãye?
2. Báwo ni mo ṣe lè gbé ìgbé ayé ìgbọràn sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
3. Kíni díẹ̀ nínú àwọn agbègbè nínú ìgbésí ayé mi níbití mo nílò láti dáríji àwọn ẹlòmíràn tàbí wá ìdáríjì?
Ronú Lórí Àwọn Òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ìyè Wọ̀nyí:
- Ọkàn alààyè dàbí àkójọpọ̀ àwọn tí ńfi ohun èlò orin oríṣiríṣi kọrin tó kún fún ìrètí àti ayọ̀, tí ń ṣeré ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run; ọkàn aṣákolọ, ìlú tí kò dún, orin tí kò dùn, ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tí kò ní ìtumọ̀.”
- Ọkàn tó wà láàyè fún Kristì ń tan ìmọ́lẹ̀, ó sì ń kó ipa rere nínú ayé ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ènìyàn, nígbàtí ọkàn tó gbádùn ayé àti ìfẹ́kùfẹ́ inú rẹ̀ paramọ́ bí òdòdó tí kò rí òòrùn láti tàn síi, àti omi láti mú-n tutù, nígbàtí ó ṣe, ẹ̀ka rẹ̀ rù, ó sì kú danù.
- Ẹ̀mí tó wà láàyè fún Kristì a máa jó nínú òjò oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nígbàtí ọkàn aṣẹ́kolọ sinmi sínú ẹkún òun ìpahín keke.
Jẹ́ Kí A Jẹ́rìí Sí Ìfarahàn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nínú Ayé Wa Pẹ̀lú Àwọn Àgbàṣẹ Ádùrá Wọ̀nyí:
1. Olúwa, ràn mí lọ́wọ́ láti gbé bí ẹ̀mí t’ó ḿbe, t’ó gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Rẹ, tí ó sì kún fún ìfẹ́ Rẹ.
2. Bàbá mi àti Ọlọ́run mi, fún mi ní ìgboyà láti pín ìhìnrere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti láti sìn Ọ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi.
3. Ẹ̀mí Mímọ́, ràn mí lọ́wọ́ láti dáríji àwọn ẹlòmíràn àti láti rí ìdáríjì gbà, kí èmi kì ó lè gbé ìgbé ayé òmìnira àti ayọ̀.
4. Olúwa fí àbò Rẹ bò mí lọ́wọ́ ìdánwò láti bá ìgbàgbọ́ mi jẹ́ àti láti gbé ìgbé ayé ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga.
5. Ẹ̀mí Mímọ́, ní gbogbo ìgbà tí O bá ńbá mi sọ̀rọ̀, fún mi ní etí ìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe , kí nlè so èso fún ìjọba Rẹ, kí ayé mi lè fi ògo àti ọlá fún orúkọ Rẹ.
Olùfẹ́ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ìtọ́sọ́nà rẹ, àti àwọn ìlérí Rẹ̀ jẹ́ orísun ìrètí àti agbára rẹ.
Nípa Ìmísí Àti Ìdarí Ẹ̀mi Mímọ́ Lafi Kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Yìí Láti Ọwọ́ Ajíhìnrere. Sefunsam Chord.