Yoruba Public Library

Yoruba Public Library Contact information, map and directions, contact form, opening hours, services, ratings, photos, videos and announcements from Yoruba Public Library, Educational Research Center, 1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park, London.

Yorùbá Public Library (Ilé ìyáwèé/kàwé gbogbogbòò Yorùbá) jẹ́ àkọ́kọ́ Ilé ìyáwèé/kàwé ajẹmọ́dííjìtì tó kó àkótán lórí Ìmọ̀ àti àṣà Yorùbá.Lára àwọn ohun tó sódo sínú náà rẹ̀ yàtọ̀ sí àwọn iṣẹ́ ajẹmọ́dííjìtì ni:Ìwádìí, agbo-ajẹmọ́ọ̀wé, ilé ìkówèé-pamọ́ sí

IGBÓ-ỌRÀIgbó-ọ̀rà wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìlú náà gbajúmọ̀ fún bíbí ìbejì, kódà a lè pè ní "olú-ìlú ìbejì ní àgbáyé. Ìwádìí...
16/09/2026

IGBÓ-ỌRÀ
Igbó-ọ̀rà wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ìlú náà gbajúmọ̀ fún bíbí ìbejì, kódà a lè pè ní "olú-ìlú ìbejì ní àgbáyé. Ìwádìí sọ pé wọn ní ọ̀bẹ̀ kan tí ó ń lapa lórí bíbí ìbejì ní ìlú náà, orúkọ ọbẹ̀ náà ni ìlasa.
Wọ́n máa ń ṣe ọdún ìbejì ní ìlú náà lọ́ọdudún, ọdún ńlá ni torí pé wọn fẹ́ràn, wọ́n sì mọ rírí àwọn ìbejì bákan náà ni wọ́n rí ìbejì bíbí gẹ́gẹ́ bí àmì ire. Igbó-ọ̀rà jẹ́ ìlú tí ó ní àṣà àti ìṣe tó yáyì.

Igbo-ọrà is located in Ọ̀yọ́ State and is famous for twins birth, we can call it the "capital of twins". Research says they consume a soup that is likened to the phenomenon of birthing twin which is called "ọbẹ̀ ìlasa.
They celebrate ọdún ìbejì annually and it is a big event because cherish and appreciate the birth of twins and it is also viewed as a symbol of goof fortune. Igbó-ọrà is a beautiful town with cultural heritage.



ÀROKÒÀrokò jẹ́ ìlò àmì láti fún ìbánisọ̀rọ̀. Ní ayé àtijọ́ àrokò jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti fi ò̩rò̩ às̩íri ràns̩é̩ ...
14/09/2026

ÀROKÒ
Àrokò jẹ́ ìlò àmì láti fún ìbánisọ̀rọ̀. Ní ayé àtijọ́ àrokò jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì láti fi ò̩rò̩ às̩íri ràns̩é̩ sí eni tó wá ní ò̩nà jínjìn, àrokò máa ń dín àròyé kù torí fúnrare̩ ni yóò túmò̩ ara rè̩. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan la fi ń pàrokò ní ilẹ̀ Yorùbá, lára àwọn tí a fi ń pa àrokò láyé ni màrìwò ọ̀pẹ́, owó ẹyọ, ìlarun, fìlà, bàtà, igbá òfìfo, ewé akòko àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Àpẹẹrẹ àrokò: tí wọ́n bá fi bàtà ẹsẹ̀ òsì ẹnìkan ráńṣẹ́ sí ẹlòmíràn, ó túmọ̀ sí pé ẹni tí ó ní bàtà náà ti kú.
Tí olùránṣẹ́ bá fi owó ẹyọ mẹ́fà sí agbaṣẹ́, ó túmọ̀ sí pé olùránṣẹ́ ń ṣe àfẹ́rí ẹni tí ó ráńṣẹ́ sí. Àrokò yìí wọ̀pọ̀ láàárín àwọn olólùfẹ́.

Àrokò is a Yorùbá non verbal communication. It was a prominent form of communication in the olden days to send important messages to a decoder at far distances, àrokò reduces frivolous discussion because it will decode itself to the decoder. There are numerous items to be used as àrokò, some of them are palm frond, cowrie, cutting comb, cap, shoe, empty calabash, akòko leaf etc. Example of àrokò: if an individual's left shoe is sent to another person as Àrokò it signifies the owner of the sandal is dead.
Six cowrie tied together signifies the sender is longing to see the reciever. This is often used between lovers.










YORÙBÁ PUBLIC LIBRARYYorùbá Public Library yoo mú kí iṣẹ́ ìwádìí lórí àṣà, èdè àti ìṣe Yorùbá rọrùn, tí yóò sì bí ọ̀tun ...
11/09/2026

YORÙBÁ PUBLIC LIBRARY
Yorùbá Public Library yoo mú kí iṣẹ́ ìwádìí lórí àṣà, èdè àti ìṣe Yorùbá rọrùn, tí yóò sì bí ọ̀tun ìjìnlẹ̀ òye àti àwọn àwárí.

Yoruba Public Library will facilitate research on Yorùbá culture, language and tradition leading to new insights and discoveries.











ÌṢELỌ́JỌ̀ ÀWỌN OÚNJẸ WA/PRESERVING OUR FOODSÀwọn ohun àjogúnbá wa ni oúnjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá, ó ń ṣàfihàn àṣà, ìṣe, ìgbàgbọ́...
09/09/2026

ÌṢELỌ́JỌ̀ ÀWỌN OÚNJẸ WA/PRESERVING OUR FOODS

Àwọn ohun àjogúnbá wa ni oúnjẹ ìbílẹ̀ Yorùbá, ó ń ṣàfihàn àṣà, ìṣe, ìgbàgbọ́ àti ìtàn wa, torí náà o se pàtàkì kí a ṣe àwọn orúkọ oúnjẹ wọ̀nyí lọ́jọ́ kódà bí a bá ń bá àwọn tí wọn kò gbọ́ èdè Yorùbá sọ̀rọ̀. Kàká kí a máa ṣe ògbufọ̀ àmàlà, àkàrà, èbìrìpò, ègbo, èkuru, ẹ̀bẹ, ìkọ́kọrẹ́, iyán, mọ́ínmọ́ín, ọ̀jọ̀jọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, a lè ṣe àpèjúwe àwọn ohun èlò, bí wọn ṣe ń sè é àti adùn rẹ̀ láì sọ orúkọ abínibí wọn nù. Ìtàn wa hànde nínú àwọn oúnjẹ wọ̀nyí, bí a bá sì ṣe àwọn orúkọ wọn lọ́jọ́, ó túmọ̀ sí pé a bọ̀wọ̀ fún ìdánimọ̀ tí wọ́n dúró fún bákan náà ni à ń mú kí àwọn ẹlòmíràn ní àǹfààní sí oúnjẹ náà tí wọ́n yóò sì ní òye nípa wọn.

Yorùbá indigenous foods are our heritage; they showcase our culture, tradition, belief, and history, which is why their original names deserve to be preserved even when speaking to non-Yorùbá audiences. Rather than translating àmàlà, àkàrà, èbìrìpò, ègbo, ẹ̀bẹ, ìkọ́kọrẹ́, iyán, mọ́ínmọ́ín, ọ̀jọ̀jọ̀ into shallow English equivalents, we can describe their ingredients, preparation, and flavour while keeping the authentic names alive. Our food carries our story, and by retaining those names, we honour the identity they hold and still make our cuisine accessible and understandable to others.












AṢỌ IṢẸ́ ÀGBẸ̀ /FARMERS’ WORK CLOTHESLáyé àtijọ́, ẹ̀wù gbérí àti ṣòkòtò dígò ni àgbẹ̀ ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ iṣẹ́ wọn. Gbér...
08/09/2026

AṢỌ IṢẸ́ ÀGBẸ̀ /FARMERS’ WORK CLOTHES
Láyé àtijọ́, ẹ̀wù gbérí àti ṣòkòtò dígò ni àgbẹ̀ ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ iṣẹ́ wọn. Gbérí àgbẹ̀ yàtọ̀ sí ti ọdẹ nítorí pé gbérí ọdẹ máa ń ní àpò níwájú àti lẹ́hìn, tíLáyé àtijọ́, ẹ̀wù gbérí àti ṣòkòtò dígò ni àgbẹ̀ ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣọ iṣẹ́ wọn. Gbérí àgbẹ̀ yàtọ̀ sí ti ọdẹ nítorí pé gbérí ọdẹ máa ń ní àpò níwájú àti lẹ́hìn, tí àgbẹ̀ kì í ní àpò. àgbẹ̀ kì í ní àpò.

In the olden days, gbérí shirts and ṣòkòtò dígò were the traditional work clothes worn by farmers. But a farmer’s gbérí was not quite the same as a hunter’s. While the hunter’s gbérí was designed with pockets at both the front and back for carrying useful items, the farmer’s was made without pockets.

© Ásà àti Ìṣe Yorùbá - CL Adéoyè











Ìmọ̀ tùÌmọ̀ jọÌmọ̀ enini kìí dalẹ́Kí ni ENINI?
07/09/2026

Ìmọ̀ tù
Ìmọ̀ jọ
Ìmọ̀ enini kìí dalẹ́

Kí ni ENINI?








Yoruba Public Library yóò ṣe àtìlẹ́hìn fún ìwádìí ajẹmákadá nípa pípèsè àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó ṣẹ́ kókó lórí ìtàn Yorùbá,...
06/09/2026

Yoruba Public Library yóò ṣe àtìlẹ́hìn fún ìwádìí ajẹmákadá nípa pípèsè àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó ṣẹ́ kókó lórí ìtàn Yorùbá, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ẹ̀sìn àti iṣẹ́ àtinudá

Yoruba Public Library will support academic research by providing relevant resources on Yorùbà history, philosophy, religion and arts












ORÚKỌ SÍSỌ/YORÙBÁ NAMINGAasà ni ọmọ ìkókó tí ó máa ń ké ní alaalẹ́Baby that cries mostly at night is called AasàKí ni wọ...
04/09/2026

ORÚKỌ SÍSỌ/YORÙBÁ NAMING
Aasà ni ọmọ ìkókó tí ó máa ń ké ní alaalẹ́

Baby that cries mostly at night is called Aasà

Kí ni wọ́n ń pè ọmọ tí ó máa ń ké tọ̀sán-tòru?









🐐 Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé èèwọ̀ ni ọ̀sìn ewúrẹ́ in Itoikin?/  Did you know that keeping goats is a taboo in Itoikin?Ewúrẹ́ jẹ́ ọ̀k...
02/09/2026

🐐 Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé èèwọ̀ ni ọ̀sìn ewúrẹ́ in Itoikin?/ Did you know that keeping goats is a taboo in Itoikin?

Ewúrẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran ọ̀sìn tí ó wọ́pọ̀ tí àwọn èèyàn máa ń sìn káàkiri pàápàá jùlọ ní ilẹ̀ Yorùbá àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ ní ìlú Itoikin ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Gẹ́gẹ́ bí Kábíèsí Ogunnoki ṣe sọ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọn pẹ̀lú Ìwé Ìròyìn The Nation, wọ́n sọ pé láyé àtijọ́ àwọn náà máa ń sin ewúrẹ́ ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan, àwọn baba ńlá wọn, wọ́n dé lọ́jọ́ kan ni wọ́n dédé rí i pé àwọn ewúrẹ́ ń rìn bi èèyàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì yìí bá wọn lẹ́rù púpọ̀, Kábíèsí orí ìtẹ́ ìgbà náà sì ráńṣẹ́ pé àwọn awo tí wọ́n bá ifá ní gbólóhùn, lédè kan, wọ́n pàṣẹ kí wọ́n pa gbogbo ewúrẹ́ inú ìlú. Láti ìgbà náà ni ọ̀sìn ewúrẹ́ ti di èèwọ̀ ní ìlú Ìtọ́kín.

While goats are common in many Yoruba towns, Ìtọ́kín town in Lagos State is different. According to Kabiyesi Ogunnoki, the people once kept goats until their forefathers returned from the farm one day to find the goats walking on their hind legs like humans! 😳 Terrified, the reigning Kabiyesi consulted the oracle and ordered all the goats in the town to be killed. Since then, keeping goats as domestic animals has remained a taboo in Itoikin.











Address

1 Thanes Villa, Seven Sister's Road, Finsbury Park
London
N77PH

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Yoruba Public Library posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The School

Send a message to Yoruba Public Library:

Shortcuts

Share