23/09/2025
Ìbẹrẹ Ránpẹ̀ (Introduction)
Fọlásadé Àgùtàsóólọ jẹ́ Ọmọ Ọdọ-Ọ̀bà, ìlú kékeré kan lẹ́bà Ọ̀yọ́-Ilé nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Fọlásadé lórúkọ abísọ rẹ̀, Àgùtàsóólọ lórúkọ ìdílé wọn tí ń gbé lókè Òdàn láìjìnì sí ilé Baálẹ̀ àgbàgbé wọn. Fọlásadé rẹ́wà púpọ̀. Adùnmaràdàn àti eléyinjú-árà nínú Yorùbá pé ìrú obìnrin bíi rẹ̀.
Fọlásadé lóyọ̀yà púpọ̀. Ìwà rẹ̀ kò ní márà. Gbogbo obìnrin àdúgbò ló fẹ́ yàn lórè, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ọdúnmọ́dé ló yàn lọ́yà. Àmọ́ ṣá, kìní kan wà tó bà Ajàọ jẹ́—bí Fọlásadé ti lẹ́wà àti ìwà tútù bí àdàbà tó kọ lórí òkùnrìn. Yorùbá bọ̀, wọ́n wí pé—Adé orí obìnrin ló je kúnrìn f’óbìnrin.
Fọlásadé r’ọ́lá f’ísadé, ṣùgbọ́n bókùnrin tó kákárí ibi gbogbo, Fọlásadé ò rókùnrin kankan f’ísadé orí. Eléyinjú-árà, kò rókùnrin f’ójú jọ. Kí ló dé? Kí ló fà? Kí ni ń bẹ lẹ́yìn ojú Fọlásadé tó f’óbìnrin mára, tó sì ń lé òkùnrin sá?