Kiko Ede Yoruba

Kiko Ede Yoruba

Share

lati lekun nipa asa ati ise yoruba ati lati moo tan imole si ohun ti o ba ru'ju. Idi ree ti e se ni

19/08/2025

Ẹ̀KỌ́ KAN🤔🤔🤔

Bí yorùbá bá fẹẹ ṣe Ìwúre pipẹ láyé fún ènìyàn, wọn a wi pe "WÀ Á PẸ́ BÍI EWÉ MỌ́PẸ́"

Irúu ewe wo ni njẹ MỌ́PẸ́?
ṣe igi ńlá ni àbí igbó lásán?
Njẹ ẹ lè rí àwòrán rẹ fún wa?
Kíni nǹkan ìyanu nípa rẹ̀?

©️ BÀBÀ LÁBÚLÉ

21/06/2025

Àṣà isomoloruko ni'lẹ̀ Yoruba

19/04/2025

Kini orúkọ tí Yoruba ń pè agbegbe yìí?

Ki sì ni orúkọ tí Yoruba ń pè inú ibi tí arábìnrin yìí wá?

19/04/2025

Ààfin isenbayei ilu Akure

19/04/2025

Gada a mi títí.

Igbo Osun osogbo leo tí ríi ni osogbo

19/04/2025

Orúkọ mìíràn fún igbó aginjù

12/03/2025

Bawo ni Yorùbá ṣe n kì ẹni tó lu MỌ́GÙN

12/03/2025

Ìjẹ̀bú ọkọ ajara

23/12/2024

*ẸYẸ NI OLÙKỌ́*

Awofin ni ẹ wo wọn,
Ẹ fojú ire wo olùkọ́,
Ojú ire làa fi wo'wo,
Ojú ire làa fi wo wúrà,
Béèyàn rí òbúrẹ́wà ẹ̀dá
Bẹ wo ó lawofin,
Yóò rẹwà nínú òbúrẹ́wà.
Béèyàn sì wò arẹwà dójú ,
Yóò rí òbúrẹ́wà nínú arẹwà,
Ọ̀rọ̀ tisa kúrò loburẹwa
Ìwà àti ẹwà wọn wọni lójú,
Wai-Wai níwà at'ẹwa wọ́n
Ntan iná ẹwà siwa lójú yanyan
Ẹyẹ ni ẹ jẹ a fi wọn we.
*Ẹyẹ lolukọ mo gba*

Ẹyẹ kò lórúko méjì,
Ẹyẹ lẹyẹ ń jẹ
Ẹyẹ'le yẹlé lóòótọ́
La ṣe ń pè wọn Ẹyẹlé ,
A ti Ẹyẹ ilé,
àti Ẹyẹ oko
Ẹyẹ lẹyẹ Ǹjẹ́
Àti àdán, àti oobẹ,
Àti ajao, afiyẹ fò
To lórí eku,
To tun ni iru nìdí
Ẹyẹ ni gbogbo wọn ń ṣé.

Bẹẹ fi olùkọ́ we Ẹyẹ ÌBAAKA,
Aroye ni wọn ń ṣe lojoojumo
Kẹ́kọ̀ọ́ lè ye ẹni tí wọn nkọ ni,
Bẹẹ fi wọn we Ẹyẹ Ipẹẹrẹ,
Ariwo onitumọ ni lọ́jọ́ gbogbo.
Ẹ fi olùkọ́ we Ẹyẹ ỌKIN
Imura wọn kasiara
Ẹ fi tisa we Ẹyẹ Oge,
Ojoojumo ni wọn fi ń wuni
Ẹ wo wọn lawofin,
Ẹ fi wọn we ẹyẹ kànnàkànnà,
Isẹ ọmọ ọlọ́mọ ni wọn ń ṣe
Wọn a sọ ọmọ ọlọ́mọ dọmọ,
Kaye ọmọ ọlọ́mọ ó lè dára.

Ẹ wo olùkọ́ sún-un,
Kẹẹ pé wọn lẸyẹ Àkókó,
Ohun tó ní ìtumọ̀
ni wọn ń fẹnu nsọ.
Ẹ pé tisa Lẹyẹ Owiwi,
Atọsan atoru wọn kii sún,
Ojoojumo ni wọn wá imọ ọtun.
Ẹ jẹ a f'olùkọ́ we Ẹyẹ Àṣà,
Wọn lọ́gbọ́n lórí,
Bẹẹni wọn gbọn ṣáṣá,
Ko si amukun mẹkọ nínú wọn.
Ẹ jẹ ká pé wọn LẸyẹlé,
Aduro tí wọn kò lẹgbẹ
Wọn kii fi akẹ́kọ̀ọ́ silẹ nígbà ìṣòro.
Ẹ pé wọn Lẹ́yẹ Òdèré
Abiamo ni wọn ń ṣe, .
Ẹ fi wọn we Ẹyẹ Odídẹrẹ́
Wọn rẹwà, bẹẹni wọn see bá ṣọrẹ

Kò sí ẹyẹ tí ẹ fi olùkọ́ we,
Tio ṣe kongẹ wọn,
Ọ̀rọ̀ tisa kúrò lọrọ Ẹyẹ Àparò,
Ọpọlọ wọn
Kò ṣeé fi wé Ẹyẹ Tin-in tin-tin
Bi Ẹyẹ lékè-lékè lo jẹ
Funfun bálau lọrọ wọn
Abiamo bíi Ẹyẹ Adìẹ ni wọn nse
Orí wọn pé bíi Ẹyẹ Kuraa
Iwuwasi wọn gan-an ọba ni
BÍI Ẹyẹ Ògòǹgò.
Ibẹru ni wọn tún jè lójú ọmọdé
Bí Ẹyẹ Asadi.

Ẹyin olùkọ́ wá àtàtà,
Kori jẹ kẹ lọla bíi Ẹyẹ Odidẹrẹ
Kẹ pẹ láyé ju arúgbó Ẹyẹ ògòǹgò lọ
Kẹ gbajumọ bí Ẹyẹ àṣà
EO ni pọn láṣọ bí Ẹyẹ Àparò láéláé
EO ni sowo tio pé bíi Ẹyẹ Adìẹ
EO ni dalarinka bí Ẹyẹ Pẹpẹyẹ
Kẹẹ doba láwùjọ bí Ẹyẹ Ògòǹgò

Want your school to be the top-listed School/college in Osogbo?

Click here to claim your Sponsored Listing.

Location

Telephone

Website

Address

Osogbo