30/09/2026
Ẹ kú ọdún, ẹ kú lúgawú ọjọ́ ìbí sí Alàgbà Kunle Afolayan
A kò le sọ̀rọ̀ nípa dídáàbòbò ati gbigbe àṣà, ìṣe, ati èdè Yorùbá lárúgẹ láì dárúkọ yín.
Nìpasẹ àwọn iṣẹ́ takuntakun yín bíi Aníkúlápó, Aráromire, ati October 1, ẹ ti gbé ògo ati ẹwà ilẹ̀ Yorùbá fihàn gbogbo àgbáyé. Ẹ jẹ́ aṣojú rere tó tọ́jú ogún àti orúkọ rere tí bàbá yín, Ade Love, fi lélẹ̀.
Àdúrà wa fún yín lónìí ni pé Ọlọ́run yóò jẹ́ kí ẹ pẹ́ fún wa nínú ètò ìlera pípé. Ọpọlọ yín kò ní dẹwọ́, ọwọ́ ìṣẹ̀dá yín kò ní tẹ bọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni àṣà Yorùbá kò ní run lọ́wọ́ yín.
Ìgbà ọdún, ọdún kan ni o! Ọjọ́ orí yín yóò dọ̀tun, ògo yín yóò sì máa tàn sí i.
Happy Birthday, Legend! The global Yoruba community celebrates you today.