Kaaro Oojiire

Kaaro Oojiire An online portal that teaches the importance of YORUBA LANGUAGE & the depth of its WISDOM amidst oth

15/12/2023
- [ ] Níbo láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tí a fi jásí ibití a jásí yìí?- [ ] Ọ̀nà wo la tọ̀ tí a fi sìnà?- [ ] Kíni a se fẹ́ se g...
05/02/2023

- [ ] Níbo láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò tí a fi jásí ibití a jásí yìí?
- [ ] Ọ̀nà wo la tọ̀ tí a fi sìnà?
- [ ] Kíni a se fẹ́ se gaan tí aó fi móríbọ́ nínú ìpayínkeke?

Ìgbòho’õsà - Májàsọ́laKòkòrò tí’n jẹ̀fọ́ fúlàní tigbòngbò-tigbòngbò, tamọtiye tí’n ta agbénipa bíi ọta-ìbọn, iwọ gangan ...
11/10/2022

Ìgbòho’õsà - Májàsọ́la

Kòkòrò tí’n jẹ̀fọ́ fúlàní tigbòngbò-tigbòngbò, tamọtiye tí’n ta agbénipa bíi ọta-ìbọn, iwọ gangan l’ọmọ “kàkà kí’mbí ẹ́gbàã ọ̀bùn, maa kúkú bí ọ̀kànsoso ọ̀gá…..” ìwọ gangan ni ìbẹ̀rù baba ìjayà, Ìgbòho’õsà tí’mba gbogbo ọ̀táã yorùbá l’ẹ́rù tilé-toko.
Ọdọọdún làá r’órógbó, ọdọọdún làá r’áwùsá, ọdọọdún làá r’ọ́mọ obì l’órí àtẹ.

Káãrọ̀ oòjíire social media platform nkí ọ pé, o kúú ìkàlẹ̀, o kúú ìfọ́mọ́nìyàn se, ọmọ-ọkọ pọ́mbélé níọ́, o kúú ìgbìyànjú àti gbé orúkọ, èdè, àsà àti ise gbogbo ilẹ̀ Káãrọ̀ oòjíire ga.

Igba ọdún, ọdún kan. Asèyí s’ẹ́ẹ̀míì t’ọmọ-t’ọmọ.

   Ọ̀ba-òkè yíó gbàwá kúrò l’ọ̀wọ̀ ìjọ̀ba ọ̀dájú, yíó sì rán aláãnú sí orílẹ̀-èdè wa!
01/10/2022

Ọ̀ba-òkè yíó gbàwá kúrò l’ọ̀wọ̀ ìjọ̀ba ọ̀dájú, yíó sì rán aláãnú sí orílẹ̀-èdè wa!

Kìnìun kìí w’ẹ̀yìn nígbàtí ajá làsàn-lásán bá n gbó. #Ẹ̀kọ́Kìí se gbogbo ẹnití ó bá n pẹ̀gàn ẹni tàbí ẹnití ó n gbèrò lá...
16/09/2022

Kìnìun kìí w’ẹ̀yìn nígbàtí ajá làsàn-lásán bá n gbó.

#Ẹ̀kọ́
Kìí se gbogbo ẹnití ó bá n pẹ̀gàn ẹni tàbí ẹnití ó n gbèrò láti ba t’ẹni jẹ́ làá mbá janpata, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn kòní ‘láárí, wọn kò ní ìbikan àá rè, adánidúró f’àsíkò-sòfò pọ́mbélé ni irúu wọn se, tórípé wọn ti fi àãrọ̀ ọjọ́ iwájú wọn sòfò dànù, èyítí ó ti sọ wọ́n di ajègbodò tó n wá ẹni kúnra.

Wò wọn bíi pé wọn kò sí níbẹ̀, kío le tètè d’ébi tí ò nlọ, ràntí wípé aníbiírè kìí dúró pàkùsọ ọ̀rọ̀ pẹ̀lù aláìníbií lọ, ibi a bá nlọ làá kọjú mọ́.

Ẹ̀ káãrọ̀, ẹ̀ kúu ojúmọ́, abátẹnijẹ́ kòní yà s’ọ́dọ̀ gbogbo wa o, Amin.

Re-post
21/08/2022

Re-post

L’óõtọ́ - ìmọ̀, ọgbọ́n, òye, agbára pẹ̀lú ìgbìyànjú leè sọni di èèyàn pàtàkì, sùgbọ́n láìsí ‘ ’ nínú àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ yìí, ó seése kí ìkòkò ọbẹ̀ oríire tí a gbé kaná kọ̀ láti jiná bọ̀rọ̀ tí gbogbo kìrà-kìtà ẹ̀dá sì leè pàdà jásí pàbó.

Àforítì ní ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ “ ”, ẹnití ó bá fẹ́ rí Àforítì, dandan ni kío gba l’álejò, tórípé bí a bá pe orí-ajá, ó di dandan kíá pe orí-ìkòkò tí a fi sèé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó wà n’ilẹ̀ se jẹ́.
Àforítì ni àgbẹ̀ bá se ọ̀rẹ́ tíó fi di ẹnití ó k’érè oko, òun ní ónísòwò bá d’òwòpọ̀ tíó fi di ẹnití ó jèrè bọ̀ ọjà, tí àforítì ẹ̀dá kòbá tó, kódà kí ìgbìyànjú rẹ̀ pọ̀ bíi omi-òkun, àseyọrí leè pàdà wá di ohun tí yíó mẹ́hẹ, èyítí yíó sì tún se tánàdí àti ní ìlọsíwájú.
Bí ẹ̀wà (erèé) kòbá l’àforítì, kòní di àkàrà táã fi njẹ ẹkọ, kátó wá sọpé kíó di èkuru, Àforítì ni ẹja fi nfi orí l’abú, àforítì ni àdán ní tíó fi leè d’oríkodò l’áwùjọ àwọn ẹyẹ, ohun ni Kìnìún fi di ọba nínú igbó, tí ó sọ Ẹkùn di olú-ọdàn, àforítì níí mú isin là, òun sì níí sọ ìyàwó di ààyò-ọkàn ọkọ.

Aláforítì kìí dẹ́já, wọn kíi sèrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, bẹ́ẹ̀ni wọn kíi sọ̀rètí nù, “bí ẹkún bá d’alẹ́, ayọ̀ mbẹ l’ówûrọ̀” ni nkan tí wọ́n fi nse agbára, bórípẹ nílẹ́, áá dire!

L’óõtọ́ - ìmọ̀, ọgbọ́n, òye, agbára pẹ̀lú ìgbìyànjú leè sọni di èèyàn pàtàkì, sùgbọ́n láìsí ‘ ’ nínú àwọn èròjà  tí a kà...
21/08/2022

L’óõtọ́ - ìmọ̀, ọgbọ́n, òye, agbára pẹ̀lú ìgbìyànjú leè sọni di èèyàn pàtàkì, sùgbọ́n láìsí ‘ ’ nínú àwọn èròjà tí a kà sílẹ̀ yìí, ó seése kí ìkòkò ọbẹ̀ oríire tí a gbé kaná kọ̀ láti jiná bọ̀rọ̀ tí gbogbo kìrà-kìtà ẹ̀dá sì leè pàdà jásí pàbó.

Àforítì ní ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́ kan tí orúkọ rẹ̀ njẹ́ “ ”, ẹnití ó bá fẹ́ rí Àforítì, dandan ni kío gba l’álejò, tórípé bí a bá pe orí-ajá, ó di dandan kíá pe orí-ìkòkò tí a fi sèé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tó wà n’ilẹ̀ se jẹ́.
Àforítì ni àgbẹ̀ bá se ọ̀rẹ́ tíó fi di ẹnití ó k’érè oko, òun ní ónísòwò bá d’òwòpọ̀ tíó fi di ẹnití ó jèrè bọ̀ ọjà, tí àforítì ẹ̀dá kòbá tó, kódà kí ìgbìyànjú rẹ̀ pọ̀ bíi omi-òkun, àseyọrí leè pàdà wá di ohun tí yíó mẹ́hẹ, èyítí yíó sì tún se tánàdí àti ní ìlọsíwájú.
Bí ẹ̀wà (erèé) kòbá l’àforítì, kòní di àkàrà táã fi njẹ ẹkọ, kátó wá sọpé kíó di èkuru, Àforítì ni ẹja fi nfi orí l’abú, àforítì ni àdán ní tíó fi leè d’oríkodò l’áwùjọ àwọn ẹyẹ, ohun ni Kìnìún fi di ọba nínú igbó, tí ó sọ Ẹkùn di olú-ọdàn, àforítì níí mú isin là, òun sì níí sọ ìyàwó di ààyò-ọkàn ọkọ.

Aláforítì kìí dẹ́já, wọn kíi sèrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, bẹ́ẹ̀ni wọn kíi sọ̀rètí nù, “bí ẹkún bá d’alẹ́, ayọ̀ mbẹ l’ówûrọ̀” ni nkan tí wọ́n fi nse agbára, bórípẹ nílẹ́, áá dire!

Address

Lagos

Opening Hours

Monday 09:00 - 17:00
Tuesday 09:00 - 17:00
Wednesday 09:00 - 17:00
Thursday 09:00 - 17:00

Telephone

+2347033137428

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Kaaro Oojiire posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The School

Send a message to Kaaro Oojiire:

Shortcuts

Share