Omidan Yorùbá

Omidan Yorùbá Yorùbá instructor, translator and lover of culture
(3)

A kú àyájọ́ àwọn ìyáẸ kú ìtọ́jú iléẸ kú ìtọ́jú ọmọẸ kú ìtọ́jú ọkọẸ ò ní jẹun ọmọ nínú u ibojìÀṣẹ!
30/03/2025

A kú àyájọ́ àwọn ìyá

Ẹ kú ìtọ́jú ilé

Ẹ kú ìtọ́jú ọmọ

Ẹ kú ìtọ́jú ọkọ

Ẹ ò ní jẹun ọmọ nínú u ibojì

Àṣẹ!




A kú Àyájọ́ Àwọn Obìnrin Ní ÀgbáyéObìnrin ni iyọ̀ ayéObìnrin ni adùn ayéObìnrin ni òpómúléró ayéLáì sí obìnrin Jú u jù u...
08/03/2025

A kú Àyájọ́ Àwọn Obìnrin Ní Àgbáyé

Obìnrin ni iyọ̀ ayé

Obìnrin ni adùn ayé

Obìnrin ni òpómúléró ayé

Láì sí obìnrin Jú u jù u

Ni ayé ì bá rí

Obìnrin ni èjìká tí kò jẹ́ kí ẹ̀wù àwọn ọkùnrin ó bọ́

Ọlọ́run kékeré àwọn ọmọ

Ẹní pé t'obìnrin báwo, àbùkù á kan onítọ̀hún





́yorùbá

Ẹ káààbọ̀ sí oṣù ÈRÈLÉ ❤️Ọpẹ́ sí Elédùà tó yọ̀ǹda èémí àti ẹ̀mí fún wà títí d'òníí🙏Adúpẹ́ oore ríríjẹ, rírína, rírílò ló...
01/02/2025

Ẹ káààbọ̀ sí oṣù ÈRÈLÉ ❤️

Ọpẹ́ sí Elédùà tó yọ̀ǹda èémí àti ẹ̀mí fún wà títí d'òníí🙏

Adúpẹ́ oore ríríjẹ, rírína, rírílò lósù ṢẸẸRẸ

Àwọn Ìbùkún ọlọkàn-ò-jọ̀kan tí a rí lósù tó kọjá kìí ṣe kèrémí... ẹ ṣeun Ẹlẹdàá 🧎

Elédùà, jọ̀wọ́ fi ire ṣe kòńgẹ́ wa lónìí àti ni gbogbo ọjọ́ tí ń bẹ lósù yìí 🙏

Ire l'ọ́tǔn l'ósì, níwájú, lẹyìn àti aarin gbùngbùn wa 🙏

Apá awọ́nrínwọ́n kìí kági, apá ọ̀tá kò nìí ká wa lóṣù yìí 🙏✅

Elédùà dákun d'áàbo bò wa tile tile, t'ẹbí t'ará 🙏

Lẹẹkansi, ẹ káàbọ̀ sí oṣù ÈRÈLÉ ❤️

kì ara tù wá gbẹ̀dẹ̀🙏

Ire o



̣


̣

01/01/2025

Ìwúre Ọdún Tuntun

A kú ọdún

A kú ìyèdú

Àṣeye ni Alákàn ń ṣe epo tiẹ̀

Àṣeye ni tiwa

Àṣetì, ò ní jẹ́ tiwa

Bí ikú bá ń ṣe pá wọn lẹ́wọrọ lẹ́wọrọ

Kí wọ́n máṣe ka tiwa mọ́ wọn

Bí wọ́n bá ń tà ikú ní épìnì

À ò ní bá wọn rà nínú ẹ̀

Bí íkú bá ń lọ ní iwájú

A ò ní ba

Bí aburú bá ń bọ̀ lẹ́yìn

Kò ní kàn wá

A ò ní rìn lọ́jọ́ ebi ń p'ọ̀nà

Ati di arikúyẹrí láti òní lọ

Ọdọọdún làá rí orógbó

Ọdọọdún làá rí awùsá

Ọdọọdún làá rí ọmọ ọbì lórí àtẹ

A ó máa ma rí ra wa tẹ̀rín tẹ̀yẹ

Ọdún á yabo fún gbogbo wa




̀

Bí ẹkún bí ẹkún ní í ṣ'egbéreBí ọ̀fọ̀ bí ọ̀fọ̀ ní í ṣ'ÀparòBí a ṣe ń lọ nínú oṣù yìíA ò ní rọ́ràn ẹkún àti ọ̀fọ̀ láṣẹ Èd...
03/11/2024

Bí ẹkún bí ẹkún ní í ṣ'egbére
Bí ọ̀fọ̀ bí ọ̀fọ̀ ní í ṣ'Àparò
Bí a ṣe ń lọ nínú oṣù yìí
A ò ní rọ́ràn ẹkún àti ọ̀fọ̀ láṣẹ Èdùmàrè
Àṣẹ



̀

Orí l'ẹja fi ń labú jáOrí wa kó lànà ayọ̀ fún waKórí má takò wá lọ́dọ̀ olóore àti aláàánúIre lojú owó ń ríIre lojú wa ó ...
25/09/2024

Orí l'ẹja fi ń labú já
Orí wa kó lànà ayọ̀ fún wa
Kórí má takò wá lọ́dọ̀ olóore àti aláàánú
Ire lojú owó ń rí
Ire lojú wa ó ma rí
Ọ̀dá owó kì í pọ́n Dàda
Ọ̀dá owó ò ní dá wa
Lónìí Ọjọ́rú, ọ̀rọ̀ wa yóò rú ọ̀tá lójú
Àṣẹ




́yorùbá
̀

Òní Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kọkànlélógún, Oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, Ọdún 2024 ni Àyájọ́ Ọjọ́ Àlááfíà lágbàáyé.       ̀    ̣àlááfíàlágbàáyé2024
21/09/2024

Òní Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kọkànlélógún, Oṣù Ọ̀wẹwẹ̀, Ọdún 2024 ni Àyájọ́ Ọjọ́ Àlááfíà lágbàáyé.




̀

̣àlááfíàlágbàáyé2024

ÌWÚRE OṢÙ TUNTUN Agbe tíí gbére pàdé olókun, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.Àlùkò tíí gbére pàdé Ọlọ́sà, yóò gbére pà...
01/09/2024

ÌWÚRE OṢÙ TUNTUN

Agbe tíí gbére pàdé olókun, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Àlùkò tíí gbére pàdé Ọlọ́sà, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Ọdídẹrẹ́ tíí gbére pàdé Olúwòó, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Ọ̀pẹ̀lẹ̀ tíí gbére pàdé Ọ̀rúnmìlà, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Àgòàlà tíí gbére pàdé òṣùpá, yóò gbére pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Tìpọ̀n ńlá onífà abìfà gbuuru;
Ìfà owó, Ìfà ọmọ, Ìfà ohun rere gbogbo ni Olódùmarè yóò gbé pàdé gbogbo wa lóṣù yìí.
Ire gbogbo yóò sun gbogbo wa bọ̀ lóṣù yìí.

Gbogbo olùṣòwò, ẹ óò rérè ọjà jẹ, òṣìṣẹ́ ìjọba, ẹ ò ní lùfin, oníṣẹ́ ọwọ́ yóò máa rí tajé ṣe. Gbogbo arìnrìn-àjò, ẹ ò níí ṣìrìn. Ọ̀gangan ọ̀nà Laláké ń sọ. Bí ẹ ti jáde nílé láyọ̀, lẹ ó ò máa padà lálàáfíà. Okó kìí jagun òbò kó má bọ̀. Àyúnlọ, àyúnbọ̀ lọwọ́ ń y'ẹ́nu.

Aboyún ilé yóò máa bí tibi tire, ewé kìí Jábọ́ lára igi kó nigi lára. Omi ò ní dànù, agbè ò ní fọ́. Baba ọmọ náà ò ní ná ọjà wàràwàrà.

Gbogbo ẹni tó wá ń sunkún àìríbí, tón gbààwẹ̀ àìrípọ̀n, Olódùmarè yóò wọlá oṣù yí, yóò sọ yín dọlọ́mọ o. A kìí wá ọmọ tì lẹ́yìn Yọ̀mọ̀tí, ọmọ yọyọ nílé aládi.

Gbogbo ẹni tó ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn lọ́wọ́lọ́wọ́, ara pápá là ń b'ẹ́tu, ibi gìjà gìjà là ń b'ẹ́kùn, ìta gbangba là ń béwé ajílékegé. Bí Alágbẹ̀dẹ bá lu irin tán, wọn á gbọn ìpẹ́ dànù. Olódùmarè yóò gbọn àìsàn nù lára gbogbo yín pátápátá. A kìí bá ọ̀kùnrùn ẹyẹ lórí ìtẹ́.

Bí a bá wá rí ohunkohun tó jẹ́ òkè ìṣòro fún ẹnikẹ́ni nínú yín tí ẹ kò le bá ẹnìkankan sọ, bí kùrukùru bá là ní sánmọ̀, a parẹ́ ni, bí òṣùmàrè bá yọ ní sánmọ̀ yóò parẹ́. Olódùmarè yóò mú ìṣòro ọ̀hún kúrò.

Gbọgbọgbọ lọwọ́ ń yọ ọ́ jorí,
Ìkéke níí lékè igi,
Òjò níí borí ọ̀dá,
Àwa la ó lékè gbogbo ìṣòro gbogbo.
Àṣẹ



́yorùbá



̣

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ kìí gbódò kó yàgànA ò ní yàgàn ohun rere lósẹ̀ yìí láṣẹ Èdùmàrè🙏🙏 🙏🙏🙏🙏       ̀
26/08/2024

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ kìí gbódò kó yàgàn
A ò ní yàgàn ohun rere lósẹ̀ yìí
láṣẹ Èdùmàrè🙏🙏
🙏🙏🙏
🙏



̀

Àìrìn jìnà làì rí abuké Ọ̀kẹ́rẹ́ Ẹní bá dẹdò jìnà á rí ọ̀nì tó yarọ.Ọkùnrin ará Faransé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ AntoineCh...
23/08/2024

Àìrìn jìnà làì rí abuké Ọ̀kẹ́rẹ́
Ẹní bá dẹdò jìnà á rí ọ̀nì tó yarọ.

Ọkùnrin ará Faransé kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Antoine
Cheval ti ṣe ìgbéyàwó alárédè fún ara rẹ̀.

Me bí tí kò bá nídìí, obìnrin kìí jẹ́ Kúmólú, Antoine Cheval ní ìdí tóun fi gbé ìgbésẹ̀ yìí nipé òun ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjákulẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn obìnrin.



Nínú gbogbo ẹ̀yà tó wà laraAhọ́n ló lágbára jùAhọ́n ló dùn jùÒhun ló korò jùOró ọmọ adáríhunrunAhọ́n ló ń gbéAdùn ọmọ èn...
15/08/2024

Nínú gbogbo ẹ̀yà tó wà lara
Ahọ́n ló lágbára jù
Ahọ́n ló dùn jù
Òhun ló korò jù
Oró ọmọ adáríhunrun
Ahọ́n ló ń gbé
Adùn ọmọ ènìyàn
Ahọn ló ń gbé
Ẹ̀yà ara pélébé
Tó lè bayé ẹni jẹ́
Ó tún lè gbé ni gun òkè ọlà
Bó ṣe kéré tó náà ló lágbára



́yorùbá

Ẹni tó wà lóríi ìdùbúlẹ̀ àìsàn nìkan ló lè moyì ìlera pípéẸni tó wà ní àtìmọ́lé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ló lè moyì òmìniraẸni òùng...
04/08/2024

Ẹni tó wà lóríi ìdùbúlẹ̀ àìsàn nìkan ló lè moyì ìlera pípé

Ẹni tó wà ní àtìmọ́lé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ló lè moyì òmìnira

Ẹni òùngbẹ ń gbẹ ló lè mọyì omi

Ẹni tó ń sùn sábẹ́ afárá ló lè mọyì ẹní

Ẹ káábọ̀ sí inú ọ̀sẹ̀ tuntun





́yorùbá

#ọ̀sẹ̀tuntun

Address

15, Kajola Road
Ifako Agege

Telephone

+2349017052383

Website

Alerts

Be the first to know and let us send you an email when Omidan Yorùbá posts news and promotions. Your email address will not be used for any other purpose, and you can unsubscribe at any time.

Contact The School

Send a message to Omidan Yorùbá:

Share

Category