07/08/2022
Iwe Ebe Itagbangba Si Baale Olunloyo,
Olunloyo Bus-Stop Akanran Road Ibadan Nigeria.
Lati Owo Dr. Daodu,
Oludijeri Ipo Aare (PRESIDENTIAL aspirant of the Social Democratic Party SDP Nigeria) fun Orile-ede Naijiria.
Ojo: 6/8/2022, Animal Hospital complex Daodu House Olunloyo Bus-Stop Akanran Road Ibadan Nigeria.
AKOLE: E BAMI BE OLOYE YIN, EZEKIEL TEMITOPE (OTOPE FOUNDATION) KO MAGBE CAMPAIGN GOMINA SEYI MAKINDE WA KAMI MO INU ILE MI, TI SENATOR FOLARIN NI MONSE LATI 2010.
Baba mi tooto,
Mo layo lati ko iwe mi yi siyin gegebii eto ti ijoba orile-ede wa Naijiria gbe kale lode-oni, f'aseyori etoo aabo-araeni-l'aaboolu (neighborhood security surveillance).
Gegebii oti jepe asiko yi gbelege to, ose pataki ki amaa fito yin leti, ki nkan otoosele, jowo eledaa wa, ki aburu ma sele siwa. Awon totisele si, ki Olorun jowo bawa dawo iru re duro.
Eo ranti wipe ayalegbe (tenant) mi ni Ogbeni EZEKIEL TEMITOPE OLADIMEJI. Eyi ti ogba ile baba mi ti mongbe, sise, ati se oselu lati odun 2003 ti moti dibo alaga kansu ninu egbee alagbado atijo All People's Party, APP.
Ni odun bii meji seyin ni apin ile naa si meji dogbandogba, ti gbogbo isale sije ti temi ati awon Omo iya mi ti aje Meje (7), ti oke sije ti awon Omo Baba mi Meje (7) eyi toku. Aseyori yi wa s'aye leyin opolopo ija, iporogan ati biba dukia je, eyi ti ofere mu emi lo.
Leyin ti alaafia ti yoju, gbogbo wa gbiyanju lati fa alaafia mora pelu wipe onikaluku nda ijoba ogun ti apin fun se, osi nda owo ree na.
Ni aarin kan ni awon Omo Baba mi gbe tenant kan wa si oke ilee naa, eyi ti o je ogun ti apin won. Eni naa ni Ezekiel Temitope OLADIMEJI. Won sope ko fi ile se oselu, office lasan l'ofee fise, iyen OTOPE foundation.
Mo fura wipe oselu lomaa nwa labe gbogbo foundation patapata. Se "gbogbo aluwala ologbo, torii ohun tio je ni".
Mo dake, mo si pinnu lati fi Aaye gba ki alaafia lee wa.
Igbayi gangan ni mofi oruko re ranse si Aafin yin wipe ki e bawa wa oye fun, kolee baa moo se daradara laarin ilu. Oruko oye ti momu wa funyin lati bami fun un nigbanaa nii ATAYESE. Mo dupe dupe wipe egbaa wole, alase OTOPE foundation si di 'ATAYESE TI ILE OLUNLOYO'.
Leyin eyi ni mori wipe oselu ponnbele lasan ni won waa gbe KAMI mole pelu gbogbo foundation ti won ngbe kiri naa, pelu if ara nira eni lara eyi to buru jai. Fun apere, o ti le ni odun kan bayi ti OTOPE ti si 'sokawe' (soak-away) inu ile wa sile, ti mosi ko leta si won t**i di oni oloni lai tun un se peluu ewu to wa ninu iruu iwa yi fun ara ilu, ni asiko yi ti orisirisi arun bii LassaFever, MonkeyPox, Covid-19 ati beebe lo, ti gba aye kan bayi. Ti ako situn mo iru arun wo lotun le de s'aye lati inu igbe tabi 'salanga' iruu eyi ti awon OTOPE FOUNDATION si simi lorun yi.
Eyi tio buruku julo ninu gbogbo re ni eyiti osele ninu ose ti alo tan ni oni yi. Awon omose OTOPE Foundation ni won waa ba mi wipe awon fe so ile wa di CAMPAIGN HEADQUARTER fun SEYI MAKINDE 2023 ELECTION.
Mosi so wipe gbogbo awa meteeta ti adijo nlo ile papo ni ao dijo joko so.
Mo fi to awon tenant keji ni ijeta, won siso wipe awon kolee fara mo peluu jagidi jagan to wa ninu oselu asiko yi.
Ipinnu awon ayalegbe keji yi ni mo si npe meeting si lowo wipe ki ajo joko so kole ye wa daradara gegebii eto ti gbogbo wa dijo ni labee ofin Naijiria.
Eleyi ni mosi ngbiyanju lati wa ona abayo si ki otoo di wipe awon eeyan kan waa fi video kan han mi nibiti arakunrin kan ti nfonnu wipe p**a ni ohun yoopa oga tia Olola julo, Eni aponle pataki, a*ofin ile igbimo a*ofin agba orile-ede Naijiria Teslim Kolawole Ajadi Folarin.
Peluu eleyi, ti gbogbo aye siti mope, akobi omo FOLARIN ni emi ise lati odun 2010 wa t**i di isinyi, nje ikoko yoo wa lee gba omi kotun gba eyin, pelu awon eeyan eniti onso oro iku l'ete bi eniti njeko yangan bayi bi?
Eyi lomumi ke gbajare sita wipe ki ebami bee Oloye yin, Ezekiel Temitope OLADIMEJI ti oni OTOPE FOUNDATION, ko jowo magbe CAMPAIGN ti Gomina Seyi MAKINDE WA kami mo'le o.
Ki ofi lilo ile na mo ni ti OTOPE FOUNDATION nikan.
Leyin eyi, ohunkohun toba sele simi, iyawo, ara, ore, omo abi ise mi, ebi iselekisele buruku eyiti kibaa je, aje wipe orun Ezekiel Temitope OLADIMEJI (OTOPE FOUNDATION) ni owa o!
Omo yin,
'Eleha' Yemisi OLADIPUPO
Amugbalegbe Eto Iroyin ati Ikede fun:
~ Dokita Folorunsho Kabiru Daodu.
Oludarii,
TessyLokan Disability Support 2023-2031.
Animal Hospital complex Daodu House Olunloyo Bus-Stop Akanran Road Ibadan Nigeria.
CC:
1)
Sen. Teslim Kolawole FOLARIN.
2)
Leader, Alhaji AbdulRashidi Folarin
3)
Alhaji Kadiri AKANBI (Otun Baale Agbe of Oyo State Nigeria)
Personal Assistant to Dr. Daodu on Politics.
4)
Chief Mrs. Ajoke AFOLABI,
Personal Assistant to Dr. Daodu on Disability Inclusion.
5)
Alhaji Daslam, Head of Alhaji M.K. Daodu's Family.
6)
Oyo State Commissioner of Police.
7)
Media Houses.
N.B.
Ileise iroyin ti ogbe iwe yi jade si aye ni:
onaaraTODAYnews and Services®
+2348115807649, [email protected]
Animal Hospital complex Daodu House Olunloyo Bus-Stop Akanran Road Ibadan Nigeria.