*ITESIWAJU EDE YORUBA*
Èrò kan ló sọ sími lókàn, mo sì ti jòkó ronú ọ̀rọ̀ yí rí, mo ké sí alárá, mo ké sí ajerò, pé kájọ jíròrò lórí ọ̀rọ̀.
Mo fi tó àwọn ènìyàn jànkàn-jànkàn létí wọ́n ní kí a máa básẹ́ lọ.
Wọ́n ní kókókó làá rán ifá adití, kẹ́kẹ́kẹ́ làá ń lu kòso, gúdúgúdú ni wọ́n lu àrán òsà, pakájá pakájà n làá gbóhùn bàtá, kí gbogbo wa ká farabalẹ̀ dí ẹ̀ wò.
Èrò ọkàn mi lórí ìtẹ̀síwájú èdè Yorùbá ló dálé, ó ǹ se mí ní kàyééfì ,ó ń semí ní hàn-àn hin-in wí pé àwọn ènìyàn le ní èròńgbà wí pé bí ó bá mà a di bì i ogún tàbí ọgbọ̀n ọdún kò ní sí nǹkan tí ń jẹ́ èdè Yorùbá mọ́ lórílẹ̀.
Bí ò bá ríbẹ̀, sèbí ó ń jọ bẹ́ẹ̀ náà ni, eégún atiro wọlé , ènìyàn atiro jáde, ẹ wo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn ò fẹ́ máa sọ Yorùbá lọ́rọ̀.
Àwọn olùkọ́ náà ńkọ́ tí wọ́n pè Yorùbá lédè ará oko, ojú gbàmí tì nígbàtí wọ́n pe Yorùbá ní fànákúlà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ìpínlẹ̀
èkó ti gbìyànjú rí, ìjọba tó kúrò níbẹ̀ se kóríyá fún wa, ẹ̀yin tí ẹ wà níbẹ̀, mo fẹ́ mu
wá bí i àbá wí pé kí ẹ tún gbé ọ̀rọ̀ Yorùbá yẹ̀wò.
Gbogbo ẹgbẹ́ tí ó jẹ́ ti èdè Yorùbá bí i àwọn ẹgbẹ́ akọ́mọlédè, (ti àwọn olùkọ́
ilé ẹ̀kọ̀ girama) ẹgbẹ́
yóósàn,(ti ọmọ akẹ́ẹ̀kọ́ ní
ilé ẹ̀kọ́ gíga) lẹ́lẹ́ka jẹ̀ka
àti ẹgbẹ́ ysan (ti àwọ́n
onímọ̀ nílé ẹ̀kọ́ gíga)
Àwọn ẹgbẹ́ àdáádálẹ̀ bíi Agbolé Yorùbá gbayì ó gbẹ̀yẹ, agbolé fèdèyangàn, ewì àjùmọ̀kọ, agbolé ìsọ̀kan, agbolé òòduà, agbolé òǹkòwé, àti
àwọn lẹ́gbẹ́-lẹ́gbẹ́, àti àwọn lọ́gbà-lọ́gbà tí wọ́n se àkólékàn lórí i títẹ̀
síwájú èdè Yorùbá, kí a se ìkéde, ìpolówó, ìpolongo
tàbí ìwọ́de wọ́ọ́rọ́wọ́
(Advocasy/rally) fún títẹ̀ síwájú èdè Yorùbá, kí a se
ti orí i fọ́n-ọ́n-rán (audio
& video) kí wọ́n má a fi se
ìpolówó èdè yorùbá
káàkiri, lóri i rédíò àti tẹlifísàn lóòrè-kóòrè, láti lè mú èdè Yorùbá tẹ̀ síwájú, kí a sì gba àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ níyànjú láti má a
kọ́ ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá.
Àwọn olùkọ́ tí wọ́n mọ tìfun tẹ̀dọ̀ èdè Yorùbá ń bẹ, ẹ kó wọn lọ́pọ̀ yanturu, kí wọ́n kọ́mọ yín lédè púpọ̀.
Ẹ jẹ́ kí n jáa yín sí nọnba kan, àwọn oyìnbó ti ń se ìwádìí lórí èdè Yorùbá ọjọ́ ti pẹ́, wọ́n ò serú ẹ̀ lórí èdè haúsá tàbí íbò, Yorùbá gan ni wọ́n ranjú mọ́, bọ́mọ oyìnbọ́ bá ń sèdè Yorùbá ẹ máa pàtẹ́wọ́ àbí?
Ohun tí wọ́n máa fi kówa lérú ní ẹlẹ́ẹ̀kejì nìyẹn, ọmọbìnrin ń dun nú pé òun ń gún yàn kò mọ̀ pé nǹkan tí yòó gbée kúrò nílé bàbá òun nìyẹn.
À ń fi àsìkò yí ké sí àwọn olórí gbogbo bíi Ààrẹ Gani Adams, Asíwájú Bọla Tinubu, Olusẹgun Ọbasanjọ, mi ò lè dárúkọ yín tán àwọn Orí adé lọ́ba lọ́ba, àti àwọn
olórí kọ̀òkan nílẹ̀ Yorùbá, ẹ̀yin páítọ̀ àti séhù séhù ni mo pè, kí wọ́n fi ọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti
mú ìtẹ̀síwájú bá èdè
Yorùbá.
Ẹ rántí pé èdè ìlú rẹ ni wàá kọ̣́kọ́ fi ronú, kí o tó sọọ́ lédè míràn.
Ẹ gbìyànjú kí ọ̀rọ̀ yí tàn ká láti ojúlé sí ojúlé, ojú òpó sí ojú òpó, ìkànnì sí ìkànnì, ọ̀dẹ̀dẹ̀ sí ọ̀dẹ̀dẹ̀, àti lórí ẹ̀rọ alátagbà kárí ayé, títí tí yóò fi dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó kàn lọ́rọ̀.
Èdè Yorùbá kò ní parun.
Ẹ seun lọ́pọ̀lọpọ̀
••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••••
*©OBEY ADEOJI ỌMỌDÉ ILE ILẸ YORÙBÁ.
®ÌLÚ ÀṢÀ
Adúláwọ̀
Whoever loses his ancestral tongue to others is equivalent to a prodigal son.
Ire ni ti wa o !
********************************************
The heartbeat of akerefinusogbon pulsing through Adúláwọ̀
Ní orúkọ Elédùmarè ni mo sí Ilé iṣẹ́ ìgbéga àṣà àti ìṣe Ọmọlúwàbí yìí. Mo gbà á ládùúrà pé a kò ní yànkú. A yóò máa léé síi ni oo.
Gbogbo ẹyin ti a pé tí ẹ jẹ ìpè ọ̀hún, inú mi dùn sí yín jọjọ. Ẹyin ìyá mi pèdè pèdè àti ẹyin baba mi. Mo dúpẹ́ ooo
Click here to claim your Sponsored Listing.